7. A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú.
8. Ìwọ yóò síṣe pẹpẹ náà ni oníhò nínú. Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fi hàn ọ́ ní orí òkè.
9. “Ìwọ yóò sí ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúsù gbọ́dọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́,
10. pẹ̀lú ogún (20) òpó àti ogún (20) ihò itẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú.
11. Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun (20) òpó àti ogún ihò itẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.
12. “Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá.