4. Òní, ní oṣù Ábíbù (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Éjíbítì.
5. Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ ẹ Kénánì, Hítì, Ámórì, Hífì àti ilẹ̀ àwọn Jébúsì; ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí.
6. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa.
7. Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín.
8. Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.’
9. Ṣiṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ìránlétí ni iwájú orí rẹ tí yóò máa ran ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.
10. Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún.