Éfésù 1:16-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi;

17. Mo sì ń bèèrè nígbàgbogbo pé kí Ọlọ́run Jésù Kírísítì Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọ̀gbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ọ́ sí i.

18. Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkan yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìreti ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́.

19. àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ agbára rẹ̀,

20. èyí tí ó fi sínú Kírísítì, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jòkòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run.

21. Ó gbé e ga ju gbogbo ìsàkóso, àti àṣẹ, àti agbára, àti ilẹ̀ ọba àti gbogbo àpèlé orúkọ tí a lè ti fún mi, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.

Éfésù 1