22. Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ Olúwa tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrin iná, ìkùukù àti òkùnkùn biribiri: Kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́. Ó sì kọ wọ́n sínú sílétì méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́.
23. Nígbà tí ẹ gbóhùn láti inú òkùnkùn wá, nígbà tí iná náà ń yọná lala, àwọn aṣáájú ẹ̀yà a yín àti àwọn alàgbà a yín tọ̀ mí wá.
24. Ẹ sì sọ pé, “Olúwa Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ hàn wá, àti títóbi rẹ̀ a sì ti gbóhùn rẹ̀ láti àárin iná wá. A ti rí i lónìí pé, ènìyàn sì lè wà láàyè lẹ́yìn tí Olúwa bá bá a sọ̀rọ̀.
25. Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú? Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run wa, àwa ó kú.
26. Ta ni nínú ẹlẹ́ran ara tí ó ti gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run láti inú iná rí, bí àwa ti gbọ́ ọ, tí a sì wà láyé?