Deutarónómì 33:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. òfin tí Móṣè fifún wa,ìní ti ìjọ ènìyàn Jákọ́bù.

5. Òun ni ọba lórí Jéṣúrúnìní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọ pọ̀,pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì

6. “Jẹ́ kí Rúbẹ́nì yè kí ó má ṣe kú,tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”

7. Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Júdà:“Olúwa gbọ́ ohùn Júdàkí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta rẹ̀!”

8. Ní ti Léfì ó wí pé:“Jẹ́ kí Túmímù àti Úrímù rẹ kí ó wàpẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.Ẹni tí ó dánwò ní Másà,ìwọ bá jà ní omi Méríbà.

9. Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,‘Èmi kò buyì fún wọn.’Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.

10. Ó kọ́ Jákọ́bù ní ìdájọ́ rẹ̀àti Ísírẹ́lì ní òfin rẹ̀.Ó mú tùràrí wá ṣíwájú rẹ̀àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.

11. Bù sí ohun ìní rẹ̀, Olúwa,kí o sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”

Deutarónómì 33