12. Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ talákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ.
13. Dá aṣọ ìlékè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó báà le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì má a jásí ìwà òdodo níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
14. Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ talákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Isírẹ́lì tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ.
15. San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣàálẹ́, nítorí ó jẹ́ talákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè képe Olúwa sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.
16. Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún bàbá wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.
17. Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlékè opó bí ẹ̀rí.