Deutarónómì 15:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní òpin ọdún méjeméje, ẹ gbọdọ̀ máa yọ̀ǹda àwọn gbéṣè.

2. Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é: Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbéṣè gbọdọ̀ fojú fo gbésè tí ó ti yá ará Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò Olúwa láti fojú fo gbésè.

3. Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjòjì. Ṣùgbọ́n ẹ fagi lé gbéṣè yóòwù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín.

4. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò tọ́ sí nínú un yín, nítorí pé Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ilẹ̀ náà tí ó ń mú un yín lọ láti gbà bí ìní yín.

5. Kìkì bí ẹ bá gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí.

6. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀ èdè tí yóò lè jọba lé e yín lórí.

7. Bí talákà kan bá wà láàrin àwọn arákùnrin yín ní èyíkèyí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí Olúwa yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe se àìláànú bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà.

8. Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò.

Deutarónómì 15