12. Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù yìí.
13. Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mósè bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, ṣíbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere Olúwa Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ ọ rẹ.
14. Olúwa kò jáfara láti mú ibi náà wá sórí wa, nítorí Olódodo ni Olúwa Ọlọ́run wa nínú u gbogbo ohun tí ó ń ṣe; ṣíbẹ̀ àwa kò ṣe ìgbọ́ran sí i.
15. “Ní ìsinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búrurú.
16. Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jérúsálẹ́mù ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédé àwọn baba wa ti mú Jérúsálẹ́mù àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.
17. “Nísinsinyìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ Olúwa, fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro.
18. Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́; ya ojú ù rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè. Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ.
19. Olúwa, fetí sílẹ̀! Olúwa, Dáríjìn! Olúwa, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.”
20. Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ Olúwa Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ.
21. Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gébúrẹ́lì ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́.
22. Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Dáníẹ́lì, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye.
23. Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àdúrà, a fún ọ ní ìdáhùn kan, èyí tí mo wá láti sọ fún ọ, nítorí ìwọ jẹ́ àyànfẹ́ gidigidi. Nítorí náà, gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò kí ìran náà sì yé ọ: