26. Ọba béèrè lọ́wọ́ ọ Dáníẹ́lì ẹni tí a tún ń pè ní Beliteṣáṣárì pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?”
27. Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àsírí tí ọba béèrè fún
28. ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àsírí hàn. Ó ti fi han ọba Nebukadinéṣárì, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:
29. “Ọba, bí ìwọ ṣe ṣùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àsírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ.
30. Ṣùgbn fún èmi, a fi àsírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀.