Dáníẹ́lì 1:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ní òpín ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá ṣíwájú ọba Nebukadinésárì.

19. Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Dáníẹ́lì, Hananíáyà, Míṣáẹ́lì àti Ásáríyà; Nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba.

20. Nínú un gbogbo ọ̀ràn, ọgbọ́n àti òyé tí ọba ń bèrè lọ́wọ́ ọ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọn tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀.

21. Dáníẹ́lì sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kìn-ín-ní ọba Kírúsì.

Dáníẹ́lì 1