Àwọn Hébérù 11:13-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o kú ní ìgbàgbọ́, láì rí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, ti wọn si gbá wọn mú, tí wọn sì jẹ̀wọ́ pé àlejò àti àtìpó ni àwọn lórí ilẹ́ ayé.

14. Nítorí pé àwọn tí o ń ṣọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn.

15. Àti ní tòótọ́, ìbáṣe pé wọn fi ìlú ti wọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí àyè padà.

16. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dá jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run: nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn; nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.

17. Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dan an wò, fi Ísáákì rúbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kanṣoṣo rúbọ,

18. Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Ísáákì ni a o ti pé irú ọmọ rẹ̀:”

19. Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìdè kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà.

20. Nípa ìgbàgbọ́ ní Ísáákì súre fún Jákọ́bù àti Ísọ̀ níti ohun tí ń bọ̀.

21. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jákọ́bù, nígbà ti o ń ku lọ, ó súrre fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù ni ìkọ̀ọ̀kan; ó sì sìn ní ìtẹriba lé orí ọ̀pá rẹ̀.

22. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jósẹ́fù, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Ísraẹ́lì; ó sì pàṣẹ níti àwọn egungun rẹ̀.

23. Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Móṣè pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí ti wọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.

24. Nípa ìgbàgbọ́ ni Móṣè, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọ-bìnrin Fáráò;

25. Ó kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgba díẹ̀.

26. Ó ka ẹ̀gàn Kírísítì si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúrà Éjípítì lọ: Nítorí tí ó ń wo èrè náà.

27. Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Éjípítì sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí.

28. Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrekọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má báa fí ọwọ́ kan wọn.

29. Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la òkun púpa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: Ti àwọn ara Éjípítì dánwo, ti wọn sì ri.

30. Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jẹ́ríkò wo lulẹ̀, lẹ̀yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ijọ́ méje.

Àwọn Hébérù 11