6. Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé,“Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”
7. Àti nípa ti àwọn ańgẹ́lì, ó wí pé;“Ẹni tí ó dá àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mi,àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ìná.”
8. Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé,“Ọlọ́run, ìjọba rẹ yóò wà láti ìran dé ìran,àti pé òdodo ni ọ̀pá tí ìwọ fi ń páṣẹ ìjọba rẹ.
9. Ìwọ fẹ́ òdodo,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú;nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi òróró ayọ̀ yàn ọtí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”
10. Ó tún sọ pé,“Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀,àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.
11. Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀gbogbo wọn ni yóò gbó di àkísà bí ẹ̀wù.
12. Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ,bí ìpàrọ̀ aṣọ ni a ó sì pàárọ̀ wọn.Ṣùgbọ́n ìwọ fúnrarẹ kì yóò yípadààti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”