Ámósì 8:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run fi hàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n.

2. Ó béèrè pé, “Ámósì kí ni ìwọ rí.”Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”

3. Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹ́ḿpìlì yóò yí padà sí ohùnréré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú-ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”

Ámósì 8