Ó béèrè pé, “Ámósì kí ni ìwọ rí.”Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”