Àìsáyà 63:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ta nì yìí tí ó ń bọ̀ láti Édómù,láti Bósírà, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí osùn ṣe àbàwọ́n fúnTa nì yìí, tí a wọ̀ ní aṣọ ẹ̀yẹ,tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀?“Èmi ni bí, tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodotí ó nípa láti gbàlà.”

2. Èéṣe tí aṣọ yín fi pupagẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí?

3. “Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì;láti àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi.Mo tẹ̀wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mimo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú miẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi,mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.

Àìsáyà 63