Àìsáyà 51:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi òkun bíàti àwọn omi inú ọ̀gbun,Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìṣàlẹ̀ òkuntó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?

11. Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin kíkọ;ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo oríi wọn.Ayọ̀ àti inú-dídùn yóò sì bà lé wọnìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

12. “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran-ara,àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,

13. tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ,ẹni tí ó ta àwọn ọ̀runtí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀,tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́nítorí ìbínú àwọn aninilára,tí wọ́n sì gbọ́kàn lé ipanirun?Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?

14. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọwọn kò ní kú sínú túbú wọn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.

15. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó ń ru òkun ṣókè tó bẹ́ẹ̀ tíìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

16. Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹmo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí àyè rẹ̀,ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,àti ẹni tí ó sọ fún Ṣhíónì pé,‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”

17. Jí, jí!Gbéra nílẹ̀ Ìwọ Jérúsálẹ́mù,ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwakọ́ọ̀bù ìbínú rẹ̀,ìwọ tí o ti fà á mu dégẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀fèrè tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀ngbọ̀nọ́n.

18. Nínú gbogbo ọmọ tí ó bíkò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ sọ́nànínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.

19. Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ—ta ni yóò tù ọ́ nínú?Ìparun àti Ìdahoro, ìyàn àti idàta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?

20. Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú;wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà,gẹ́gẹ́ bí ẹtu tí a dé mọ́nú àwọ̀n.Ìbínú Olúwa ti kún inú un wọn fọ́fọ́ọ́fọ́àti ìbáwí Ọlọ́run yín.

Àìsáyà 51