14. Ó gé igi kédárì lulẹ̀,tàbí bóyá ó mú Ṣípírẹ́sì tàbí óákù.Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó,ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.
15. Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kíara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tíó sì ń sìn ín;ó yá ère, ó sì ń forí balẹ̀ fún un.
16. Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;lóríi rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,“Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”
17. Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;ó forí balẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,“Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”
18. Wọn kò mọ nǹkankan, nǹkankan kò yé wọn;a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkankan;bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkankan.
19. Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òyeláti sọ wí pé,“Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kannínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”