2 Sámúẹ́lì 8:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Dáfídì sì kọlu àwọn Fílístínì, ó sì tẹrí wọn ba: Dáfídì sì gba Metegamímà lọ́wọ́ àwọn Fílístínì.

2. Ó sì kọlu Móábù, ó sì fi okùn títa kan dìwọ́n, ó sì dá wọn dùbúlẹ̀; ó sì ṣe òṣùwọ̀n okùn méjì ni iye àwọn tí yóò dá sí. Àwọn ará Móábù sì ń sin Dáfídì, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá.

3. Dáfídì sì kọlu Hadadésérì ọmọ Rehóbù, ọba Sóbà, bí òun sì ti ń lọ láti mú agbára rẹ̀ bọ̀ sípò ni odò Éfúrétì.

4. Dáfídì sì gba ẹgbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àti ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rin ẹlẹ́ṣin, àti ẹgbàawá àwọn ẹlẹ́sẹ̀: Dáfídì sì já gbogbo àwọn ẹṣin kẹ̀kẹ́ wọn ní pátì, ṣùgbọ́n ó dá ọgọ́rún kẹ̀kẹ́ sí nínú wọn.

5. Nígbà tí àwọn ará Síríà ti Dámásíkù sì wá láti ran Hadadésérì ọba Sóbà lọ́wọ́, Dáfídì sì pa ẹgbàámọ́kànlá ènìyàn nínú àwọn ará Síríà.

2 Sámúẹ́lì 8