2 Sámúẹ́lì 6:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà tí wọ́n sì dé ibi ìpakà Nákónì, Úsà sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dì í mú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀.

7. Ibínú Olúwa sì ru sí Úsà; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣìṣe rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.

8. Inú Dáfídì sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Úsà kúrò: ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresí-Úsà títí ó fi di òní yìí.

9. Dáfídì sì bẹ̀rù Olúwa ní ijọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí-ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?”

10. Dáfídì kò sì fẹ́ mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dáfídì; ṣùgbọ́n Dáfídì sì mú un yà sí ilé Obedì-Édómù ará Gátì.

11. Àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedì-Édómù ará Gátì ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedì-Édómù, àti gbogbo ilé rẹ̀.

12. A sì rò fún Dáfídì ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedì-Édómù, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dáfídì sì lọ, ó sì mú àpótí-ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedì-Édómù wá sí ìlú Dáfídì pẹ̀lú ayọ̀.

2 Sámúẹ́lì 6