2 Sámúẹ́lì 22:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dáfídì sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.

2. Ó sì wí pé,“Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi;

3. Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,àti ìwọ ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi,àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi;ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.

4. Èmi képe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn,ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

5. “Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.

6. Ọ̀já isà-òkú yí mi káàkiri;ìkẹ́kùn ikú dojú kọ mí.

2 Sámúẹ́lì 22