8. Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Ísírẹ́lì àti ti Júdà fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ ẹ̀ lọ.
9. Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gan ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Ùráyà ará Hítì, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.
10. Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúró ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Úráyà ará Hítì láti ṣe aya rẹ.’
11. “Bàyìí ni Olúwa wí, Kíyèsí i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrun yìí.
12. Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀: Ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Ísírẹ́lì, àti níwájú òòrun.’ ”
13. Dáfídì sì wí fún Nátanì pé, “Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa!”Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, “Olúwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú.
14. Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀ta Olúwa láti sọ ọ̀rọ̀ òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.”
15. Nátanì sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi àrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Úráyà bí fún Dáfídì, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀.
16. Dáfídì sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dáfídì sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dúbúlẹ̀ lorí ilé ni orú náà.
17. Àwọn àgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé: ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.