17. Dáfídì sì fi orin arò yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Ṣọ́ọ̀lù àti lórí Jónátanì ọmọ rẹ̀,
18. Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Júdà ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jáṣárì):
19. “Ogo rẹ, Ísírẹ́lì ni a pa ní òkè gíga rẹ.Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!
20. “Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gátì,ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Áṣíkélónì,kí àwọn ọmọbìnrin Fílístínì má bá à yọ̀,kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má baà dunnú.
21. “Ẹ̀yin òkè Gílíbóà,kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò,tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá.Nítorí ibẹ̀ ni aṣà alágbára ti ṣègbé,aṣà Ṣọ́ọ̀lù, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.