17. Ṣùgbọ́n wọ́n forítì í títí ojú fi tì í láti gbà. Ó wí pé, “Rán wọn.” Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò ríi.
18. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Èlíṣà, tí ó dúró ní Jẹ́ríkò, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”
19. Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Èlíṣà, pé “Wò ó, Olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà kò dára ilẹ̀ náà sì jẹ́ aṣálẹ̀.”
20. Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un.
21. Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà ṣá.’ ”