Ní ọdún kẹsàn-án ti Hóṣéà, ọba Áṣíríà mú Ṣamáríà ó sì kó Ísírẹ́lì lọ sí Áṣíríà. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hálà, ní Gósánì ní ọ̀dọ̀ Hábónì àti ní ìlú àwọn ará Médáì.