2 Kíróníkà 6:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “Nísinsinyìí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, pa ìlérí tí ó ti ṣe mọ́ fún ìransẹ́ rẹ Dáfídì baba mi nígbà tí o wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ kù láti ní ọkùnrin láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Isírẹ́lì, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n bá kíyèsíara nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí òfin mi gẹ́gẹ́ bí o sì ti ṣe.’

17. Nísinsìnyí, Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti sèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì kí ó wá sí ìmúṣẹ.

18. “Ṣùgbọ́n ṣé Ọlọ́run nítòótọ́ yóò máa bá àwọn ènìyàn gbé lórí ilẹ̀ ayé bí? Ọ̀run, àti ọ̀run gíga kò le gbà ọ́. Báwo ni ó ṣe kéré tó, ilé Olúwa tí mo ti kọ́!,

19. Síbẹ̀ ṣe àfiyèsí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi, gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ.

20. Kí ojú rẹ kí ó lè sí sí ilé Olúwa ní ọ̀sán àti lóru, ní ibí yìí tí ìwọ ti wí pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ síbẹ̀. Kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà lórí ibí yìí.

2 Kíróníkà 6