1. Ábíjà sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dáfídì. Ásà ọmọ rẹ̀ rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, orílẹ̀ èdè wà ní àlàáfíà fún ọdun mẹ́wàá.
2. Ásà ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́ ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
3. Ó gbé àwọn pẹpẹ àjèjì kúrò àti àwọn ibi gíga. Ó fọ́ àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀, ó sì gé àwọn òpó Áṣérà bolẹ̀.
4. Ó pa á láṣẹ fún Júdà láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wọn àti láti tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ àti àṣẹ.