1 Tẹsalóníkà 5:14-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrin yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ̀pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.

15. Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ maa lépa èyí tíi ṣe rere láàrin ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.

16. Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo

17. Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo

18. Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kírísítì Jésù nítòótọ́.

19. Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́.

20. Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń ìsọtẹ́lẹ̀.

21. Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú.

22. Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi.

23. Kí Ọlọ́run àlàáfíà pàápàá wẹ̀ yín mọ́, kí ó sì yà yín sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́, títí di ìgbà wíwá Jésù Kírísítì Olúwa wa.

24. Olótítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.

25. Ẹ̀yin ará, ẹ gbàdúrà fún wa.

26. Ẹ gbà ara yín ní ọwọ́ ní orúkọ mi pẹ̀lú ọkàn funfun.

27. Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́ta yìí fún gbogbo àwọn ará.

28. Ki oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín. Àmín.

1 Tẹsalóníkà 5