1 Tẹsalóníkà 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yin pàápàá mọ̀, ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán.

2. Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Fílípì bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìyìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle.

3. Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í se ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè.

4. Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í se bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò se Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò.

1 Tẹsalóníkà 2