20. Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”
21. Nígbà tí Sámúẹ́lì gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa.
22. Olúwa dáhùn pé, “Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn.”Nígbà náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé, “Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀.”