1. Nígbà tí Sámúẹ́lì di arúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún Ísírẹ́lì.
2. Orúkọ àkọ́bí rẹ̀ a máa jẹ́ Jóẹ́lì àti orúkọ ẹ̀kejì a máa jẹ́ Ábíjà, wọ́n ṣe ìdájọ́ ní Bíáṣébà.
3. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.
4. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbààgbà ti Ísírẹ́lì péjọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà.
5. Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsìn yìí, yan ọba fún wa kí or lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀ èdè”
6. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa” Èyí kò tẹ́ Sámúẹ́lì lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa.
7. Olúwa sì sọ fún un pé: “Tẹ́tí sí gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ fún ọ; kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.
8. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Éjíbítì títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ.
9. Nísinsìn yìí, gbọ́ ti wọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáadáa, kí o sì jẹ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”