1 Sámúẹ́lì 8:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Sámúẹ́lì di arúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún Ísírẹ́lì.

2. Orúkọ àkọ́bí rẹ̀ a máa jẹ́ Jóẹ́lì àti orúkọ ẹ̀kejì a máa jẹ́ Ábíjà, wọ́n ṣe ìdájọ́ ní Bíáṣébà.

3. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.

4. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbààgbà ti Ísírẹ́lì péjọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà.

1 Sámúẹ́lì 8