23. Dáfídì sì wí pé, “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi: Olúwa ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́-ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́.
24. Ta ni yóò gbọ́ tiyín nínú ọran yìí? Ṣùgbọ́n bi ìpín ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ si ìjà ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ti ó dúró ti ẹrù; wọn ó sì pín in bákan náà.”
25. Lati ọjọ́ náà lọ, ó sì pàṣẹ, ó sì sọ ọ di òfin fún Ísírẹlì títí di òní yìí.
26. Dáfídì sì padà sí Síkílágì, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbà Júdà, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀ta Olúwa wa.”
27. Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Bẹ́tẹ́lì àti sí àwọn tí ó wà ní Gúúsù tí Rámótì, àti sí àwọn tí ó wà ní Játírì.
28. Àti sí àwọn tí ó wà ní Áróérì, àti sí àwọn tí ó wà ní Sífímótì, àti sí àwọn tí ó wà ni Ésítémóà.
29. Àti si àwọn tí ó wà ni Rákélì, àti sí àwọn tí ó wà ní ìlú àwọn Jérámélì, àti sí àwọn tí ó wà ni ìlú àwọn ará Kéni.
30. Àti sí àwọn tí ó wà ni Hórímà, àti àwọn ti ó wà ní Kórásánì, àti sí àwọn tí ó wà ni Átakì.
31. Àti àwọn tí ó wà ni Hébírónì, àti sí gbogbo àwọn ilú ti Dáfídì tìkárarẹ̀ àti tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń rìnká.