1 Sámúẹ́lì 2:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Hánà sì gbàdúrà pé:“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;Ìwọ agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀ta mi,nítorí ti èmi yọ̀ ni igbala rẹ̀

2. “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;kò sí ẹlòmíràn bí kò se ìwọ;kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.

3. “Má ṣe halẹ̀;má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jádenítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.

1 Sámúẹ́lì 2