1 Sámúẹ́lì 1:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.”

17. Élì dáhùn pé, “Má a lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”

18. Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọbinrin náà bá tirẹ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.

19. Wọ́n sì díde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rámà: Elikánà si mọ aya rẹ̀: Olúwa sì rántì rẹ̀.

20. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ rẹ̀ pé, lẹ́yìn ìgbà tí Hánà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, pé, “Nítorí tí mo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ Olúwa.”

1 Sámúẹ́lì 1