1 Pétérù 1:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrétí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

22. Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnikejì yín gidigidi láti ọkàn wá.

23. Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láàyè tí ó sì dúró.

1 Pétérù 1