1 Ọba 8:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Sólómónì pe àwọn àgbà Ísírẹ́lì àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ papọ̀ níwájú rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù, láti gbé àpótí-ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wá láti ìlú Dáfídì, tí ń ṣe Ṣíónì.

2. Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì pe ara wọn jọ sọ́dọ̀ Sólómónì ọba ní àkókò àjọ ọdún ní oṣù Étanímù tí íṣe osù kéje.

3. Nígbà tí gbogbo àwọn àgbà Ísírẹ́lì dé, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí-ẹ̀rí,

4. wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa àti àgọ́ àjọ ènìyàn àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sì gbé wọn gòkè wá,

5. Àti Sólómónì ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí-ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rúbọ.

6. Àwọn àlùfáà sì gbé àpótí-ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀ sínú ibi tí a yà sí mímọ́, ibi mímọ́ ilé náà, jùlọ lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.

7. Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí-ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí-ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e.

1 Ọba 8