26. Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Bẹni-Hádádì ka iye àwọn ará Árámù, ó sì gòkè lọ sí Áfékì, láti bá Ísírẹ́lì jagun.
27. Nígbà tí a sì ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì pèsè oúnjẹ, wọ́n sì lọ pàdé wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dó níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ewúrẹ́ kékeré méjì, nígbà tí àwọn ará Árámù kún ilẹ̀ náà.
28. Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Árámù rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”