Bénáyà sì wọ inú àgọ́ Olúwa, ó sì wí fún Jóábù pé, “Ọba sọ wí pé, Jáde wá.”Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Èmi yóò kú níhìn ín.”Bénáyà sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Jóábù ṣe dá mi lóhùn.”