1 Kọ́ríńtì 3:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fi hàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olùkúlùkú ṣe wò.

14. Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀.

15. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárin iná kọjá.

16. Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín?

1 Kọ́ríńtì 3