1 Kọ́ríńtì 1:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, ẹni ti a pé láti jẹ́ àpósítélì Kírísítì Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sósíténì arákùnrin wa.

2. Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọ́ríńtì, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Jésù Kírísítì àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà.

3. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jésù Kírísítì.

4. Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kírísítì Jésù.

5. Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo.

6. Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kírísítì ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín.

7. Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyì ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì.

8. Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì.

9. Ọlọ́run, nípaṣẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa, jẹ́ Olótítọ́.

10. Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé kí gbogbo yín fohùnsọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyàpá láàrin yín, àtipé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.

11. Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kiloe sọ di mímọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrin yín.

12. Ohun tí mo ń sọ ni pé: Olúkúlùku yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Pọ́ọ̀lù”; “Èmi tẹ̀lé Àpólò”; òm̀íràn, “Èmi tẹ̀lé Kéfà, ìtúmọ̀, Pétérù”; àti ẹlòmìíràn, “Èmi tẹ̀lé Kírísítì.”

13. Ǹjẹ́ a há pín Jésù bí? Ṣé a kan Pọ́ọ̀lù mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀yín bọmi yín ní orúkọ Pọ́ọ̀lù bí?

14. Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọmi yàtọ̀ sí Kírísípù àti Gáíù.

15. Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnraara mi.

16. (Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Sítéfánà bọmi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọmi mọ́ níbikíbi).

17. Nítorí Kírísítì kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n Ó rán mi láti máa wàásù ìyìn rere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébú Kírísítì dí aláìlágbára.

1 Kọ́ríńtì 1