Sek 1:16-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nitorina bayi li Oluwa wi; mo padà tọ̀ Jerusalemu wá pẹlu ãnu; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, a o kọ ile mi sinu rẹ̀, a o si ta okùn kan jade sori Jerusalemu.

17. Ma ke sibẹ̀ pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; A o ma fi ire kún ilu-nla mi sibẹ̀; Oluwa yio si ma tù Sioni ninu sibẹ̀, yio si yàn Jerusalemu sibẹ̀.

18. Mo si gbe oju mi soke, mo si ri, si kiyesi i, iwo mẹrin.

19. Mo si sọ fun angeli ti o ba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi? O si da mi lohùn pe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda, Israeli, ati Jerusalemu ka.

20. Oluwa si fi gbẹnàgbẹnà mẹrin kan hàn mi.

21. Nigbana ni mo wipe, kini awọn wọnyi wá ṣe? O si sọ wipe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda ka, tobẹ̃ ti ẹnikẹni kò fi gbe ori rẹ̀ soke? ṣugbọn awọn wọnyi wá lati dẹruba wọn, lati le iwo awọn orilẹ-ède jade, ti nwọn gbe iwo wọn sori ilẹ Juda lati tu u ka.

Sek 1