O. Daf 65:6-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nipa agbara rẹ̀ ẹniti o fi idi òke nla mulẹ ṣinṣin; ti a fi agbara dì li àmure:

7. Ẹniti o pa ariwo okun mọ́ rọrọ, ariwo riru-omi wọn, ati gìrìgìrì awọn enia.

8. Awọn pẹlu ti ngbe apa ipẹkun mbẹ̀ru nitori àmi rẹ wọnni: iwọ mu ijade owurọ ati ti aṣalẹ yọ̀.

9. Iwọ bẹ aiye wò, o si bomi rin i: iwọ mu u li ọrọ̀, odò Ọlọrun kún fun omi: iwọ pèse ọkàn wọn, nigbati iwọ ti pèse ilẹ bẹ̃.

10. Iwọ fi irinmi si aporo rẹ̀ pipọpìpọ: iwọ si tẹ́ ogulutu rẹ̀: iwọ fi ọwọ òjọ mu ilẹ rẹ̀ rọ̀: iwọ busi hihu rẹ̀.

11. Iwọ fi ore rẹ de ọdun li ade; ọrá nkán ni ipa-ọ̀na rẹ.

O. Daf 65