5. Ọfa rẹ mu li aiya awọn ọta ọba; awọn enia nṣubu nisalẹ ẹsẹ rẹ.
6. Ọlọrun, lai ati lailai ni itẹ́ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ, ọpá-alade otitọ ni.
7. Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ.
8. Gbogbo aṣọ rẹ li o nrun turari, ati aloe, ati kassia, lati inu ãfin ehin-erin jade ni nwọn gbe nmu ọ yọ̀.
9. Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri.
10. Dẹti silẹ, ọmọbinrin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ!
11. Bẹ̃li Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sìn i.
12. Ọmọbinrin Tire ti on ti ọrẹ; ati awọn ọlọrọ̀ ninu awọn enia yio ma bẹ̀bẹ oju-rere rẹ.