13. Ki a ke ati ọmọ-de-ọmọ rẹ̀ kuro, ati ni iran ti mbọ̀ ki orukọ wọn ki o parẹ.
14. Ki a ma ranti ẹ̀ṣẹ awọn baba rẹ̀ lọdọ Oluwa; má si jẹ ki a nù ẹ̀ṣẹ iya rẹ̀ nù.
15. Jẹ ki nwọn ki o wà niwaju Oluwa nigbagbogbo, ki o le ke iranti wọn kuro lori ilẹ.
16. Nitori ti kò ranti lati ṣãnu, ṣugbọn o ṣe inunibini si ọkunrin talaka ati olupọnju nì, ki o le pa onirobinujẹ-ọkàn.
17. Bi o ti fẹ egun, bẹ̃ni ki o de si i: bi inu rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ̃ni ki o jina si i.