Luk 21:32-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ.

33. Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

34. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọ̀bia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi, ti ọjọ na yio si fi de ba nyin lojijì bi ikẹkun.

35. Nitori bẹni yio de ba gbogbo awọn ti ngbe ori gbogbo ilẹ aiye.

36. Njẹ ki ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura nigbagbogbo, ki ẹ ba le là gbogbo nkan wọnyi ti mbọ̀ wá iṣẹ, ki ẹ si le duro niwaju Ọmọ-enia.

37. Lọsán, a si ma kọ́ni ni tẹmpili; loru, a si ma jade lọ iwọ̀ lori òke ti a npè ni oke Olifi.

38. Gbogbo enia si ntọ̀ ọ wá ni tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, lati gbọ́rọ rẹ̀.

Luk 21