11. Ẹnyin kò gbọdọ jale, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe alaiṣõtọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣeké fun ara nyin.
12. Ẹnyin kò si gbọdọ fi orukọ mi bura eké, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.
13. Iwọ kò gbọdọ rẹ́ ẹnikeji rẹ jẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ haramu: owo ọ̀ya alagbaṣe kò gbọdọ sùn ọdọ rẹ titi di owurọ̀.
14. Iwọ kò gbọdọ bú aditi, tabi ki o fi ohun idugbolu siwaju afọju, ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA.
15. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ: iwọ kò gbọdọ gbè talaka, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe ojusaju alagbara: li ododo ni ki iwọ ki o mã ṣe idajọ ẹnikeji rẹ.
16. Iwọ kò gbọdọ lọ soke lọ sodo bi olofófo lãrin awọn enia rẹ: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ró tì ẹ̀jẹ ẹnikeji rẹ: Emi li OLUWA.
17. Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
18. Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹ̃ni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fẹ́ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA.
19. Ki ẹnyin ki o pa ìlana mi mọ́. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ẹranọ̀sin rẹ ki o ba onirũru dàpọ: iwọ kò gbọdọ fọ́n daru-dàpọ irugbìn si oko rẹ: bẹ̃li aṣọ ti a fi ọ̀gbọ ati kubusu hun pọ̀ kò gbọdọ kan ara rẹ.
20. Ati ẹnikẹni ti o ba bá obinrin dàpọ, ti iṣe ẹrú, ti a fẹ́ fun ọkọ, ti a kò ti ràpada rára, ti a kò ti sọ di omnira; ọ̀ran ìna ni; ki a máṣe pa wọn, nitoriti obinrin na ki iṣe omnira.
21. Ki ọkunrin na ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ani àgbo kan fun ẹbọ ẹbi.
22. Ki alufa ki o si fi àgbo ẹbọ ẹbi ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da: a o si dari ẹ̀ṣẹ ti o da jì i.
23. Ati nigbati ẹnyin o ba si dé ilẹ na, ti ẹnyin o si gbìn onirũru igi fun onjẹ, nigbana ni ki ẹnyin kà eso rẹ̀ si alaikọlà: li ọdún mẹta ni ki o jasi bi alaikọlà fun nyin; ki a máṣe jẹ ẹ.
24. Ṣugbọn li ọdún kẹrin, gbogbo eso rẹ̀ na ni yio jẹ́ mimọ́, si ìyin OLUWA.