Lef 13:34-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò pipa na; si kiyesi i bi pipa na kò ba ràn si awọ ara, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju; nigbana ni ki alufa ki o pè e ni mimọ́: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ mimọ́.

35. Ṣugbọn bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara rẹ̀ lẹhin ìpenimimọ́ rẹ̀;

36. Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara, ki alufa ki o máṣe wá irun pupa mọ́; alaimọ́ ni.

37. Ṣugbọn li oju rẹ̀ bi pipa na ba duro, ti irun dudu si hù ninu rẹ̀; pipa na jiná, mimọ́ li on: ki alufa ki o pè e ni mimọ́.

38. Bi ọkunrin kan tabi obinrin kan ba ní àmi didán li awọ ara wọn, ani àmi funfun didán;

39. Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi àmi didán li awọ ara wọn ba ṣe bi ẹni ṣe funfun ṣe dudu; ifinra li o sọ jade li ara; mimọ́ li on.

Lef 13