1. Kro 23:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Awọn ọmọ Amramu; Aaroni ati Mose: a si ya Aaroni si ọ̀tọ, ki o le ma sọ awọn ohun mimọ́ jùlọ di mimọ́, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai, lati ma jo turari niwaju Oluwa, lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀ lailai.

14. Ṣugbọn niti Mose enia Ọlọrun, a kà awọn ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ ẹ̀ya Lefi.

15. Awọn ọmọ Mose ni, Gerṣomu ati Elieseri.

16. Ninu awọn ọmọ Gerṣomu, Sebueli li olori.

17. Awọn ọmọ Elieseri ni Rehabiah olori. Elieseri kò si li ọmọ miran; ṣugbọn awọn ọmọ Rehabiah pọ̀ gidigidi.

18. Ninu awọn ọmọ Ishari; Ṣelomiti li olori.

19. Ninu awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ekini, Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, ati Jekamami ẹkẹrin.

20. Ninu awọn ọmọ Ussieli: Mika ekini, ati Jesiah ekeji.

21. Awọn ọmọ Merari; Mali ati Muṣi. Awọn ọmọ Mali; Eleasari ati Kiṣi.

22. Eleasari kú, kò si li ọmọkunrin bikòṣe ọmọbinrin: awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Kiṣi si fẹ wọn li aiya.

23. Awọn ọmọ Muṣi; Mali, ati Ederi, ati Jeremoti, mẹta.

1. Kro 23