Awọn ọmọ Amramu; Aaroni ati Mose: a si ya Aaroni si ọ̀tọ, ki o le ma sọ awọn ohun mimọ́ jùlọ di mimọ́, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai, lati ma jo turari niwaju Oluwa, lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀ lailai.