2. Ile na ti Solomoni ọba kọ́ fun Oluwa, gigun rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ibú rẹ̀, ogun igbọnwọ, ati giga rẹ̀, ọgbọn igbọnwọ.
3. Ati ọ̀dẹdẹ niwaju tempili ile na, ogún igbọnwọ ni gigùn rẹ̀, gẹgẹ bi ibú ile na: igbọnwọ mẹwa si ni ibú rẹ̀ niwaju ile na.
4. Ati fun ile na ni a ṣe ferese fun síse.
5. Lara ogiri ile na li o bù yàra yika; ati tempili, ati ibi-mimọ́-julọ, li o si ṣe yara yika.
6. Yara isalẹ, igbọnwọ marun ni gbigbòro rẹ̀, ti ãrin, igbọnwọ mẹfa ni gbigbòro rẹ̀, ati ẹkẹta, igbọnwọ meje ni gbigbòro rẹ̀, nitori lode ogiri ile na li o dín igbọnwọ kọ̃kan kakiri, ki igi-àja ki o má ba wọ inu ogiri ile na.
7. Ile na, nigbati a nkọ́ ọ, okuta ti a ti gbẹ́ silẹ ki a to mu u wá ibẹ li a fi kọ́ ọ, bẹ̃ni a kò si gburo mataka, tabi ãke, tabi ohun-elo irin kan nigbati a nkọ́ ọ lọwọ.